Ecclesiastes 6

1Mo ti rí ibi mìíràn lábẹ́ oòrùn. 2Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ọlá àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohunkóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfààní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn. Asán ni èyí, ààrùn búburú gbá à ni.

3Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́ọ̀rún ọmọ kí ó sì wà láààyè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, síbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láààyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo sọ wí pé ọlẹ̀ ọmọ tí a sin sàn jù ú lọ. 4Ó wà láìní ìtumọ̀, ó lọ nínú òkùnkùn, nínú òkùnkùn sì ni orúkọ rẹ̀ fi ara pamọ́ sí. 5Bí ó ti jẹ́ wí pé kò rí oòrùn tàbí mọ ohunkóhun, ó ní ọ̀pọ̀ ìsinmi ju ti ọkùnrin náà lọ. 6Kódà, bí ó wà láààyè fún ẹgbẹ̀rún ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun ìní rẹ̀. Kì í ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ?

7Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ ni
síbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí
8Kí ni àǹfààní tí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní
lórí aṣiwèrè?
Kí ni èrè tálákà ènìyàn
nípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tókù?
9Ohun tí ojú rí sàn
ju ìfẹnuwákiri lọ
Asán ni eléyìí pẹ̀lú
ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

10Ohunkóhun tí ó bá ti wà ti ní orúkọ,
ohun tí ènìyàn jẹ́ sì ti di mí mọ̀;
kò sí ènìyàn tí ó le è ja ìjàkadì
pẹ̀lú ẹni tí ó lágbára jù ú lọ
11Ọ̀rọ̀ púpọ̀,
kì í ní ìtumọ̀
èrè wo ni ènìyàn ń rí nínú rẹ̀?
12Àbí, ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún ènìyàn ní ayé fún ọjọ́ ayé kúkúrú àti asán tí ó ń là kọjá gẹ́gẹ́ bí òjìji? Ta ni ó le è sọ fún mi, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn lẹ́yìn tí ó bá lọ tán? Kò sí!

Copyright information for YorBMYO